ÌGBỌ̀NRÌRÌ[1]

Chimamanda Adichie (tí Kọ́lá Túbọ̀sún túmọ̀)

Lọ́jọ́ tí bàálù jábọ̀ ní Nigeria, ọjọ́ tí ìyàwó ààrẹ orílẹ̀-èdè kú, ẹnìkan kàn’lẹ̀kùn gbọ̀ngbọ̀n n’ilé Ukamaka ní Princeton. Kíkànlẹ̀kùn yìí yàá lẹ́nu nítorí àwọn ènìyàn kìí wá s’ẹ̀nu ọ̀nà rẹ̀ láìsọtẹ́lẹ̀. Ó sì múu bẹ̀rù nítorí láti àárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ yẹn ló ti wà lóríi íntánẹ́ẹ́tì tó ti ń ka ìròyìn láti Nigeria, tó ń tún ojú ìwé íntánẹ́ẹ́tì ṣí ní gbogbo ìgbà. Àwọn àwòrán tó rí láti ibi tí bàálù yìí ti jábọ́ ni ó ti patì. Gbogbo ìgbà tó bá wò wọ́n, á tan ìmọ́lẹ́ ojú ẹ̀rọ kọ̀mpútà rẹ̀ láti wo oun tí àwọn oníròyìn ń pè ní ‘ìṣẹ́kù ìjàmbá’ — gudugbẹ̀ dúdú pẹ̀lú àwọn oun funfun lára rẹ̀ bíi bébà tí a já wẹ́lẹwẹ̀lẹ; kundu bí èédú nísìnyí, oun tó jẹ́ ọkọ̀ ojú òfurufú tí àwọn èèyàn ń wà nínú ẹ̀ nígbàkanrí.

Ìkan nínú àwọn èèyàn yìí tiẹ̀ lè jẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àtijọ́: Udenna.

Kíkànlẹ̀kùn yìí tún dún síi, ní líle. Ó yọjú wo inú ihò ìlẹ̀kùn: ọmọkùnrin dúdú kúkurú kan tó dàbí ẹni tó ti rí rí, bí kò tiẹ̀ le rántí ibi tó ti mọ̀ọ́. Ó ṣílẹ̀kùn. Ó rẹ́rìín músẹ́ díẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ láì wo ojú ẹ̀. ‘Ọmọ Nigeria ni mí. Àjà kẹta ni mò ń gbé. Mo ní kí n wá kí á baà le jọ gbàdúrà ni nípa ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀ èdèe wa.’

Ó yàá lẹ́nu pé ọmọkùnrin yìí mọ pé ọmọ Nigeria lòun ńṣe, pé ó mọ ibi tóun ń gbé nínú ilé yìi, pé ó sì ti wá láti wá kànlẹ̀kùn ẹ̀; kò sì tíì rántí ibi tí òun ti mọ̀ọ́ rí.

‘Ṣé mo lè wọlé?’ ìyẹn bèèrè.

Ó jẹ́ kó wọlé. Ó jẹ́ kí ọkùnrin àjèjì tó wọ aṣọ Princeton, tó fẹ́ wá báa gbàdúrà nípa oun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nigeria, wọ inú ilé rẹ̀; nígbà tí tibí sì nawọ́ síta láti dìí lọ́wọ́ mú, ó ròó díẹ̀ pèré kó tó gbà fúun.

***

Ó gbàdúrà bí àwọn Onígbàgbọ́ ìgbàlódé Nigeria yẹn tí kò báa lára mu púpọ̀; ó dáàbòbo gbogbo ǹkan pẹ̀lú ẹ̀jẹ Jésú, ó ń de gbogbo ànjọ̀nú, ó sì ń sọ wọ́n sínú òkun. Ó ń bá àwọn ẹ̀mí òkùnkùn púpọ̀ jà. Ukamaka fẹ́ dáa dúró, ó fẹ́ sọ fúun pé eléyìí ò pọndandan, gbogbo títú dídè ẹ̀jẹ̀ yìí, gbogbo sísọ ìgbàgbọ́ di iṣẹ́ ìjàkadì; ó fẹ́ sọ fúun pé ilé ayé jẹ́ ìjàkadì pẹ̀lú ara ẹni ju pẹ̀lú Sàtání olọ́kọ̀ lọ; pé ìgbàgbọ́ jẹ́ oun tí ẹ̀rí ọ̀kan wa gbọdọ̀ yàn láti wà ní ìgbaradì.

Tibí gbàdúrà gbàdúrà, ó ń ju ọwọ́ tèyí sókè nígbà tó bá ń sọ ‘Bàbá olúwa ọlọ́run o!’ tàbí ‘lórúkọ Jésù!’ Nígbà tó yà, Ukamaka ríi pé ara òun bẹ̀rẹ̀ sí ń gbọ̀nri — gbogbo ara ẹ̀ ń gbọ̀nrìrì — láìròtì. Ṣé ọlọ́run lèyí? Nígbàkanrí, lọ́dún púpọ̀ sẹ́yìn, nígbà tó wà lọ́mọgẹ, nígbà tó máa ń ka rósárì rẹ̀ láìdúró láráàárọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ kan tí kò yé òun gaan ti jáde lẹ́nu ẹ̀ níbi tó ti kúnlẹ̀ sí etí igi ibùsùn rẹ̀. Kò pẹ́ ju bíi ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀ lọ, àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yé ẹnìkankan tó jáde lẹnu rẹ̀ láàárín Mo Kí Ọ Màríà, ṣùgbọ́n ìgbà tó parí kíka rósárì, ẹ̀rù bàá gidigidi; ó rò dájú pé ìfọ̀kànbalẹ̀ funfun tó dàbo òun nígbà yẹn ni oun tí wọn ń pè ní Ọlọ́run.

Nísinsìnyí, gbígbọ̀n yìí dúró lọ́gán bó ṣe bẹ̀rẹ̀, ọmọkùnrin Nigeria yìí sì parí àdúrà náà. ‘Ní orúkọ ńlá àìnípẹ̀kun ti Jésù!”

‘Àmín!’ ó dáhùn.

Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò ní ti tiẹ̀, ó ní ‘Mò ń bọ̀’, ó sì yára lọ sí balùwẹ̀. Nígbà tó jáde, ọmọkùnrin yìí ṣì dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé ìdáná.

‘Orúkọ mi ni Chinedu,’ ó sọ fúun.

‘Ukamaka ni t’èmi,’ òun náà dáhùn.

‘Ìjàmbá bàálú yìí burú jáì.’ Ó tún wí. ‘Ó burú jáì’

‘Bẹ́ẹ̀ni.’ Kò sọ fúun pé Udenna tiẹ̀ lè wà nínúu ìjàmbá náà. Ó lérò pé yóò máa lọ, ṣèbí wọ́n ti gbàdúrà tán, ṣùgbọ́n ó kọjá sí inú yàrá ìgbàlejò, ó jókòó lóríi àga, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ bó ṣe gbọ́ nípa ìjàmbá náà, bí ẹni pé arábìnrin yìí ní kó dúró ti òun. Ó sọ fúun pé òun ò tiẹ̀ mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ méjì ni — ìyàwó ààrẹ orílẹ̀ èdè ti kú ní orílẹ̀-èdè Spain lẹ́yìín iṣẹ́ abẹ fún ikùn ní ìgbaradì fún ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún-un rẹ̀, nígbà tí bàálú já l’Ékòó lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn tó gbéra kọjú sí Àbújá.

‘Mo mọ ẹnìkan tó wà nínúu ọkọ̀ tó já yìí,’ Ukamáká wí. ‘Tó lè wà nínú ọkọ̀ yẹn.’

‘Ọlọ́run Jèhófa!’

‘Ọ̀rẹ́kùnrin mi Udenna. Ọ̀rẹ́kùnrin mi àtijọ́ ṣá. Ó ń ṣe MBA lọ́wọ́ ní Wharton tẹ́lẹ̀ ni, ó dẹ̀ lọ sí Nigeria lọ́sẹ̀ tó kọjá fún ìgbéyàwọ́ mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan.’ Ó ti sọ̀rọ̀ tán kó tó ríi pé òún lo ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn láti sọ nípa Udenna.”

‘Ṣé oò dẹ̀ tíì gbọ́ ǹkankan dájú?” Chinedu bèèrè.

‘Rárá. Kò ní fóònù alágbèéká ní Nigeria, mi ò sì rọ́nà bá ọmọ ìyá’bìnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀. Bóyá wọ́n jọ wà pọ̀ ni. Ọ̀la ló yẹ kí ìgbéyàwó yìí wáyé l’Ábùújá.’

‘Ọlọ́run kò yípadà. Ọlọ́run kò yípadà!’ Chinedu gbóhùn-un rẹ̀ sókè. Ọlọ́run kò yípadà. Ṣóo gbọ́ mi?’

Pẹ̀lú ìbẹ̀rù díẹ̀, Ukamaka ní ‘Bẹ́ẹ̀ni.’

Fóònù dún. Ukamaka tẹjú mọ́ọ, fóònù dúdú aláìlókùn tó ti fi sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ẹ ẹ̀rọ kọ́mpútà alágbèékáa rẹ̀, pẹ̀lú ìbẹ̀rù láti gbée.

Chinedu dìde bí ẹni pé ó fẹ́ lọ múu. Ukamaka ní ‘Rárá!’, ó múu fúnra è, ó sì rìn lọ sí ibi fèrèsé. ‘Ẹ̀ló? Ẹ̀ló?’ Ó fẹ́ kí ẹni tó wà níbẹ̀ sọ oun tó bá fẹ́ sọ ní kíákíá láì kọ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọdùn. Ìyá ẹ̀ ni.

‘Ọmọ mi, Udenna wà lálàáfíà. Chikaodili ṣẹ̀ṣẹ̀ pè mí tán ni, láti sọ fún mi pé wọn kò bá ọkọ̀ lọ. Ó wà pa. Ó yẹ kán wà lórí ọkọ̀ yẹn ṣùgbọ́n wọ́n pẹ́ dé. A dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run.’

Ukamaka gbé fóònù sílẹ̀ lóríi pèpéle fèrèsé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. Lákọ̀ọ́kọ́, Chinedu dìímú l’éjìká. Lẹ́yìn èyí, ó fàá mọ́ra. Ó dákẹ́ diẹ̀ kó baà lè sọ fúun pé Udenna wà l’álàáfíà, kó tó padà sínúu ìfàmọ́ra ẹ̀; ó yàá lẹ́nu pàápàá bí ó ṣe fií lọ́kàn balẹ̀ tó. Ó dáa lójú pé ọmọkùnrin yìí ti mọ̀ pé ẹkún ẹ̀ wá láti ìbàlẹ̀ ọkàn nípa oun tí kò ṣẹlẹ̀ àti ìrẹ̀wẹ̀sì-ìbànújẹ́ oun tí ò bá ti ṣẹlẹ̀, àti láti ìbínú àwọn oun tí kò tíì yée láti ìgbà tí Udenna ti sọ fúun, nínú ilé ìtaja yìnyín ẹlẹ́rìndòdò ní Òpópónà Nassau, pé ìbáṣepọ̀ wọn ti parí.

‘Mo mọ pé ọlọ́run-un mi yóò ṣè’gbàlà! Mo ti ń gbàdúrà nínú ọkàn mi fún ọlọ́run láti paámọ́,’ Chinedu sọ, bí ó ṣe ń f’ọwọ́ paá lẹ́yìn.

Nígbà tó yá, lẹ́yìn tó ti sọ fún Chinedú kó dúrò tìí fún oúnjẹ ọ̀sán, tó sì ti gbé ọbẹ̀ díẹ̀ lená nínú ẹ̀rọ amóú́njẹgbóná, ó bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀, ‘Tí o bá ní pé ọwọ́ ọlọ́run ni ìpamọ́ Udenna wà, ó túmọ̀ sí wípé ọlọ́run ló mú kí àwọn tó kú kú, nítorípé ọlọ́run ì bá ti mú wọn wà láàyè pẹ̀lú. Ṣé èyí túmọ̀ sí pé ọlọ́run fẹràn àwọn kan ju àwọn kan lọ ni?’

‘Ọ̀nà Ọlọ́run kìi ṣe ọ̀nàa tiwa.’ Chinedu bọ̀ bàtàa ẹ̀, ó sì kó wọn s’ẹ́gbẹ̀ẹ́ẹ pèpèle ìkówèésí.

‘Kò mọ́gbọ́n wá.

‘Ọlọ́run máa ń ṣìṣe ọgbọ́n ṣùgbọ́n kìí ṣe irú ọgbọ́n ti àwa ènìyàn,’ Chinedu sọ, bó ṣe ń wo àwọn àwòrán tó wà lóríi pèpélé ìwée olùgbàlejò ẹ̀. Irú ìbéèrè tí Ukamaka máa ń bèèrè lọ́wọ́ọ Fadá Patrick, bótilẹ̀jẹ́wípé Fadá Patrick máa ń faramọ́ọ pé ọlọ́run kìín mọ́gbọ́n wá ní gbogbo ìgbà, pẹ̀lúu ìsọ̀jìkáa ẹ̀ bó ṣe ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ pàdé ẹ̀, nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan láàárín ọdún tí Udenna sọ fúun pé ó ti parí. Òun àti Udenna ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nínúu Thomas Sweet níbi tí wọ́n ti ń mu omi arẹ̀dòdò ọ̀gẹ̀dẹ̀ àti èso, tí wọ́n máa ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ Àìkú lẹ́yìn tí wọ́n bá ra oun èlò ilé tán, tí Udenna ti ń fa tiẹ̀ mu pẹ̀lú ariwo kó tó sọ fúun pé ìbáṣepọ̀ wọn ti parí tipẹ́tipẹ́, wípé wọ́n kàn wà papọ̀ gẹ́gẹ́ torí pé ó ti mọ́ra ni, ó sì tẹjú mọ́ọ, ó ń retí ẹ̀rín, bó tiẹ̀ jẹ́ wípé kìí ṣe ìwàa rẹ̀ láti fi ǹkan báyìí ṣeré. ‘Runlé’ ni ọ̀rọ̀ tó lò. Kò ní ẹlòmíràn o, ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ náà ti ń runlé. Runlé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òún ti ń to ìgbésí ayée rẹ̀ yíiká fún ọdún mẹ́ta. Runlé, síbẹ̀ òún ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ àbúrò ìyáa rẹ̀ lẹ́nu, ìyẹn Sẹ́nétọ̀, nípa bíbáa wálé sí Àbújá lẹ́yìn tó bá parí ilé ìwé gíga nítorí Udenwa fẹ́ kó padà wá sílé lẹ́yìn tó bá parí ìwé onímọ̀ gíga ẹ̀ láti wá bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣètò oun tó pè ní ‘ọrọ̀ òṣèlú’ fún ìdíje ẹ̀ fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra. Runlè, síbẹ̀ ó ń se oúnjẹ ẹ̀ pẹ̀lú ata súẹ́súẹ́ nísìnyí, gẹ́gẹ́ bó ṣe nífẹ́ẹ rẹ̀ gaan. Ó kúrò ní Thomas Sweet, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn réderèdelọ sí Òpópónà Nassau àti padà sísàlẹ̀ títí tó fi kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ẹ ilé ìjọ́sìn olókuta aláwọ̀ eérú, ó sì yàbàrá wọlé, ó sì sọ fún ọkùnrin tó wọ kọ́là funfun tó fẹ́ wọnú Sùbárù rẹ̀ pé ilé ayé ò m’ọ́gbọ́n wá. Ìyẹ́n sọ fúun pé orúkọ òhun ni Patrick Fadá àti pé ilé ayé kò mọ́gbọ́n wá ṣùgbọ́n gbogbo wa la ṣì nílò láti ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀. Ní ìgbàgbọ́. ‘Ní ìgbàgbọ́’ dàbíi pé kí a ní kí èèyàn ga tàbí ṣe róndó. Ó fẹ́ ga kó sì ṣe róndó ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀; ó kúrú, ìdíi ẹ̀ sì pẹlẹ̀bẹ, ibi jẹ̀bẹ̀jẹ̀bẹ̀ alágídí kékeré kan níbi ìsàlẹ̀ ikùn ẹ̀ ta síta, kódà nígbà tó bá wọ Amáraṣegírí Spanx ẹ̀, pẹ̀lú aṣọ oníjánú tó fún mọ́ ni lára. Nígbà tó sọ èyí, Fadá Patrick rẹ́rìín.

‘“Ní ìgbàgbọ́” kò dàbíi sísọ pé kí èèyà ga tàbí ṣe róndó. Ó dà bíi sísọpé kí èèyàn faramọ́ ikùn yíyọ díẹ̀ àti wíwọ Spanx,’ ó wí fúun. Òun náà rẹ́rìín pẹ̀lú, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu pé ọkùnrin aláwọ̀ funfun yìí pẹ̀lú onírun fàdákà mọ oun tí Spanx jẹ́.

Ukamaka bu ọbẹ̀ ata díẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ẹ ìrẹsì tó ṣèṣẹ̀ mú gbóná lóríi abọ́ Chinedu. Chinedu mú ẹ̀mú ìjẹun tó fi sóríi abọ́ ẹ̀ sókè. ‘Jọ̀wọ́ fún mi ní ṣíbí.’

Ó fúun níkan. Udenna ìbá rí Chinedu fi ṣe yẹ̀yẹ́, ìbá sọ bó ṣe jẹ́ ìwà oko láti fi ṣíbí jẹ ìrẹsì bí Chinedu ṣe ń ṣeé, tó ń dìí mú pẹ̀lú gbogbo ìka ẹ̀ — Udenna pẹ̀lú agbára ẹ̀ láti tẹjú mọ́ àwọn èèyàn kí ó sì mọ̀, nípa ìdurósí àti bàtàa wọn, irúu ọmọdé tí wọ́n ṣe látìbẹ̀rẹ̀.

‘Udenna nìyẹn, abí?’ Chinedu nawọ́ sí fọ́tọ̀ tó wà nínúu férémù alágbọ̀n, níbi tí ọwọ́ Udenna ti da bòó léjìká, ojú àwọn méjèèjì ní ṣíṣí àti pẹ̀lú ẹ̀rín.

‘Bẹ́ẹ̀ni, Udenna ńláa nì nìyẹn o.’ Ukamaka dínjú, ó sì jọ́kòó sí oríi tábìlì ìjẹun pẹ̀lú abọ́ oúnjẹ ẹ̀. ‘Mo máa ń gbàgbé láti yọ àwòrán náà kúrò ni.’ Irọ́ ni o. Ó ti wòó láìmọye ìgbà láàárín oṣù tó kọjá, nígbàmíràn láì mọ̀ọ́mọ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìbẹ̀rù ìparípátá àti sọ̀ọ́ kalẹ̀. Ó níran pé Chinedu gaan mọ̀ pé irọ́ lòun ń pa.

‘A pàdé ní ayẹyẹ ìparí ẹ̀kọ́ yunifásitì ọmọ-ìyá mi obìnrin lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn ní New Haven. Òrẹ́ẹ wọn kan ló múu dání. Ó ń ṣiṣẹ́ ní Wall Street nígbà yẹn, èmí dẹ̀ wà ní ilé ìwé akẹ́kọ̀ọ́gboyè níbí, ṣùgbọ́n a mọ púpọ̀ nínú àwọn èèyàn kannáà láti Philadelphia. Òun lọ sí U Penn fún yunifásitì ìbẹ̀rẹ̀, èmí sì lọ sí Bryn Mawr. Ó panilẹ́rìín pé a ní àìmọye ǹkan tí a fi jọra ṣùgbọ́n a ò pàdé títí dìgbàyẹn.’

‘Ó dàbí ẹni tó ga,’ Chinedu sọ, ó ṣì wà lẹ́gbẹ́ẹ̀ pèpéle ìwé pẹ̀lúu abọ́ oúnjẹ ẹ lọ́wọ́ ẹ̀.

‘Ìwọ̀n ẹsẹ̀ẹ bàtà mẹ́fà àti ẹyọ mẹ́rin ni.’ Ó ń gbọ́ ìgbéraga nínú ohùn ara ẹ̀. ‘Àwòrán ẹ̀ tó dáa jù kọ́ nìyẹn. Ó jọ Thomas Sankara gaan. Mo nífẹ̀ẹ́ ìyẹn gaan nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. Ṣóo mọ̀ọ́, ààrẹ Burkina Faso, ààrẹ olókìkí, èyí tí wọ́n pa—’

Á-a, bẹ́ẹ̀ni mo mọ Thomas Sankara.’ Chinedu wo àwòrán ọ̀ún dáadáa fún ìgbà díẹ̀, bíi pé ó ń wá ìran ìdárasíi Sankara níbẹ̀. Ó wá ní, ‘Mo rí ẹ̀yin méjèèjì lẹ́ẹ̀kan níta nílé ìgbọ́kọ́sí, mo sì mọ̀ pé Nigeria lẹ ti wá. Mo fẹ́ wá fira mi hàn ṣùgbọ́n mo ń kánjú láti lọ wọ ọkọ̀ nígbà yẹn.’

Ó kó ara ẹ̀ ní ìjánu láti má bèèrè wípé kíni ní pàtó ni Chinedu rántí: Ṣé ó rí ọwọ́ Udenna tó dúró níbi kọ́lọ́fín ẹ̀yìn ẹ̀? Ǹjẹ́ ó rí Udenna tó ń báa tàkurọ̀sọ oge, pẹ̀lú ojúu wọn pẹ́kípẹ́kí?

‘Ṣé ọbẹ̀ ata yẹn ti ta jù ni?’ Ó bèèrè, bó ṣe ríi bí Chinedu ṣe ń yọ́ jẹun.

‘Ó dáa. Jíjata tiẹ̀ ti mọ́ mi lára. Èkó ni mo ti dàgbà.’

‘Èmi ò fẹ́ràn oúnjẹ aláta títí tí mo fi pàdé Udenna. Mi ò tiẹ̀ mọ̀ bóyá mo fẹ́ràan ẹ̀ báyìí.’

‘Ṣùgbọ́n o ṣì ń sèé.’

Kò fẹ́ràan bó ṣe sọ èyí, kò sí fẹ́ràn pé ojù ẹ̀ wà ní pípadé, láì fi ààyè sílẹ̀ fún yíyẹ̀wò, bó ṣe wòó ní kíámọ́sá tó sì gbójú padà sí orí àwo ẹ̀. Ukamaka ní, ‘Ẹn, ṣebí ó ti bá mi lára mu báyìí.’

Ó tẹ bọ́tìnì kan lóríi ẹrọ ayárabíàṣá àgbélétan ẹ̀, mú ojú ìwé ayélujára kan bọ̀wásípò. Gbogbo Èmí Ṣòfò Nínú Bàálú Tó Já Ní Nigeria. Ìjọba ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo ẹ̀tàdínlọ́gọ́fà èèyàn tó wà lóríi bàálù náà lo ti kú.

‘Kò sí ẹnìkan tó yè,’ ó wí.

‘Baba, gbàkóso,’ Chinedu sọ, ó sì mí kanlẹ̀ lọ́nà tí gbogbo èèyàn le gbọ́. Ó wá jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ láti kà lóríi ẹ̀rọ kọ̀mpútà àgbélétan ẹ̀, ara wọn típẹ́típẹ́, òórùn ọbẹ̀ ata ẹ̀ lórí èémí ẹ̀. Àwọn àwòrán míì lári ibi ìjàmbá yìí wà níbẹ̀. Ukamaka tẹjú mọ́ ìkan lára àwọn ọkùnrin tí kò wọ bùbá tó ń gbé irin tó dàbíi irin ibùsùn tó kákò; kò le fojú sun apá bàálú tí èyí le ti wá.

Láwọn ọjọ́ tó tẹ̀lée, àwọn ọjọ́ tó ti tutu díẹ̀ fúun láti wọ bàtà aláwọ tó dé orúnkún, àwọn ọjọ́ tó wọ ọkọ̀ lọ sí ọgbá ilé ẹ̀kọ́, se ìwádìí ìṣẹ́ ìmọ̀ọ rẹ̀ nínú yàrá ìkówèésí, pàdée olùdámọ̀ràn ẹ̀, kọ́ kíláàsì àròkọ ọ̀dọ́langba yunifásitìi rẹ̀, á wá padà sí ilée rẹ̀ nírọ̀lẹ́ láti dúró de Chinedu kó wá kíi kó baà lè fúun ní ìrẹsì tàbí pizza tàbí spaghetti. Kó báa lè báa sọ̀rọ̀ nípa Udenna. Ó fẹ́ràn pé Chinedu kìí sọ̀rọ̀ púpọ̀, ó máa ń wò bíi pé kò kàn gbọ́ oun tó ń sọ lásán, ṣùgbọ́n pé ó ń ronú síi oun tó ń sọ pẹ̀lú. Lẹ́ẹ̀kan rí, ó ronú nípa bí báa ní àjọṣepọ̀, bí báa ṣe eré oge ìpadàbọ̀, ṣùgbọ́n ó dà bíi pé nǹkankan wà lára rẹ̀ tí kìí fẹ́ ṣe ìbálòpọ̀, èyí sì dùn mọ́ọ nínú, nǹkankan wà nípa ẹ̀ tó jẹ́ kí Ukamaka rò pé òun ò nílò láti fi àtíkè pa abẹ́ ojú ẹ̀ láti fi àwọn oun dúdú ibẹ̀ pamọ́.

Ibùgbé rẹ̀ kún fún àwọn àjèjì mìíràn. Òun àti Udenna máa n ṣe yẹ̀yẹ́ pé àìṣeégbọ́kànlé agbègbè tuntun àwọn àjèjì yìí ni ó darapọ̀ di àìbìkítà tí wọ́n fi ń han ara wọn. Wọn kìí kí ara wọn nínú ọgbà tàbí inú ẹ̀rọ agbénigòkèàjà, wọn kìí sì wo ara wọn lójú nínúu ìrìn-àjò ìṣẹ́jú márùún lóríi ọkọ̀ àárín ọgbà, àwọn oníṣẹ́ ọpọlọ gbajúmọ̀ yìí láti Kenya àti China àti Russia, àwọn akẹ́kọ̀ọ́gboyè àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n-kékeré tí wọ́n máa jáde lọ láti darí tàbí ṣe ìwòsàn tàbí ṣe àtúndá ilé ayé. Nítorí náà, ó yàá lẹ́nu pé bí òun àti Chinedu ṣe ń rìn lọ sí ilé ìgbọ́kọ̀sí, ó má juwọ́ sí ẹnìkan, á sì sọ ‘ẹ ǹ lẹ́ o’ sí òmíràn.

‘Ṣé o mọ̀ wọ́n láti inú ètò rẹ ni?’ ó bèèrè.

Ó ti sọ ǹkan fúun rí nípa ìmọ̀ kẹ́místítì, ó sì rò pé ìkẹ́kọ́gboyè dókítà ló ń ṣe. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìdí èyí tí òun ò fi ń ríi ní ọgba; iyàrá iṣẹ́ẹ sáyẹ́nsì jìnà púpọ̀ ó sì sàjèjì.

‘Rárá. Mo pàdée wọn nígbà tí mo dé ni.’

‘Báwo ló ṣe pẹ́ tó tí o ti ń gbé ibi?’

‘Kò pẹ́. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ni. Mo mọ̀ pé mo ní láti gbìyànjú láti ní ọ̀rẹ́ nínúu ilé yìí. Lọ́nà míì wo ni mo ṣe fẹ́ dé ilé ìrajà oúnjẹ àti ilé ìjọ́sìn? Olúwaṣeun pé ìwọ́ ni mọ́tò,’ ó wí.

Lọ́jọ́ Ìsinmi, ó wa Chinedu lọ sí ilé ìjọ́sìn Pentecostal tó wà ní Lawrenceville kí òun tó lọ sí ilé ìjọ́sìn Kátólíkì tó wà ní Òpópónà Nassau. Nígbà tó bá sì tún gbée padà lẹ́yìn ìsìn, wọ́n lọ ra èròjà oúnjẹ ní McCaffrey’s. Ó sàkíyèsí iye oúnjẹ kékeré tó rà àti bó ṣe máa ń wò fínihfíní àwọn àkọlé ìtajà oníbébà tí Udenna máa ń yìnnù.

‘Ebi ń pamí. Ṣé ká lọ ra sanwich níbìkan?’

‘Mo ń gbààwẹ̀,’ ó sọ lóùn ilẹ̀.

‘Oh.’ Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ langba, òun náà máa ń gbààwẹ̀, tí á mu omi nìkan láti àárọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún odidi ọ̀sẹ̀ kan, láti bèèrè lọ́wọ́ ọlọ́run láti ràánlọ́wọ́ láti ní èsì tó dáa jù níní ìdánwòo Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga. Ipò kẹta ló gbà l’ésì.

‘Abájọ tí oò fi jẹ ìrẹsì kankan lánàá,’ ó ní. ‘Ṣé wàá jókòó pẹ̀lú mi bí mo ṣe ń jẹun ṣá?’

‘Ehn.’

‘Ṣé àdúrà pàtàkì kan lo ń ṣe ni? Àbí ǹkan àṣírí pàtàkì tí mi ò le bèèrè?’

‘Nǹkan àṣírí pàtàkì ni. Oò lè bèèrè,’ Chinedu sọ pèlú ohùn ẹ̀gàn àti ìbọ̀wọ̀fún.

Ó mú fèrèsè ọkọ̀ wá sílẹ̀ bó ṣe ń gbé ìdí ọkọ̀ jáde nínú ilé ìgbọ́kọ̀sí. Ó dúró lári jẹ́ kí àwọn obìnrin méjì tí wọn ò wọ aṣọ òtútù kọjá. Wọ́n wọ jínsì tó mọ́ wọn lára pẹ́kípẹ́kí, irun aláwọ̀ wúràa wọn sì ń fẹ́ lẹ́lẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan pẹ̀lú atẹ́gùn. Ojú ọjọ́ lọ́wọ́rọ́ ju bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ ní àsìkò ìparí ọdún báyìí.

‘Àsìkò ìparí ọdún yìí máa ń rán mi létíi ìgbà ọyẹ́,’ Chinedu sọ.

‘Mo mọ̀,’ Ukamaka fèsì. ‘Mo fẹ́ràan ìgbà ọyẹ́. Mo rò pé nítoríi Ọdún Kérésìmesì ni. Mo fẹ́ràan gbígbẹ àti eruku Kérésìmesì. Udenna àt’èmi jọ padà lọ fún Kérésìmesì lọ́dún tó kọjá, ó sì ṣe Ọjọ́ Ọdún Tuntun pẹ̀lú àwọn òbí mi ní Nimo. Àbúrò ìyá mi ọkùnrin ṣáà ń bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀: “Ọmọkùnrin, ìgbà wo lo máa mú àwọn ẹbí ẹ wá láti wá kànlèkùun wa?”’ Ukamaka ṣe ohùn gbẹ̀gẹ̀dẹ̀, Chinedu sì rẹ́rìín.

‘Ǹjẹ́ o ti padà sílé láti lọ kí wọn láti ìgbà tí o ti kúrò?’ Ukamaka bèèrè. Bó sì ṣe bèèrè tán, ó kábàámọ̀ pé òún bèèrè. Ó yẹ kó ti mọ̀ pé Chinedu ò lè lówó láti wọkọ̀ lọ kí wọn nílé.

‘Rárá.’ Ohùn ẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì.

‘Ṣé wàá padà sílé tóo bá ti parí níbí? Mo ń ronú gbogbo iye owó tóo máa gbà ní ìkan nínú àwọn ilé iṣẹ́ epo ti Niger Delta, pẹ̀lú ìmọ̀ dókítà ẹ.’ Ó mọ̀ pé òun ń sáré sọ̀rọ̀ jù, pẹ̀lú ìkálòlò, lọ́nàkọnà láti bo ìnira ẹ̀ mọ́lẹ̀.

‘Mi ò mọ̀.’ Chinedu ò tiẹ̀ rẹ́rìín músẹ́ púpọ̀. Ukamaka wa ọkọ ní jẹ̀lẹ́ńkẹ́ lọ sí ibi tí wọ́n ti ń ta sandwich; ó ń kan orí mọ́lẹ̀ sí orin inúu rẹ́díò lati fihàn pé òun ń gbádùun ẹ̀ bí ó ṣe dàbíi pé Chinedu náà ń ṣe.

‘Màá kàn gba sandwich yẹn ni,’ Ukamaka sọ, Chinedu sì l’óun máa dúró sínúu mọ́tò. Gbogbo òórùn ayú láti inúu sandwich ẹran adìyẹ tí a fi bẹ́bà onírin wé ni ó gba inúu ọkọ̀ kan nígbà tó padà dé.

‘Fóònù ẹ dún,’ Chinedu ní.

Ukamaka gbé fóònù alágbèéká ẹ̀, ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì wòó. Rachel, ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan láti kíláàsì ẹ̀ ni, bóyá ó ń pè láti mọ̀ bóyá ó fẹ́ lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ lóríi ìhùwàsí àti kíkọ̀wẹ́ ìtàn ní East Pyne lọ́jọ́ kejì.

‘Mi ò tiẹ̀ gbàgbọ́ pé Udenna ò tíì pè mí,’ Ukamaka sọ, ó sì tanná sí mọ́tò. Udenna ti fi ìfirahnṣẹ́ ayárabíàṣá ránṣẹ́ síi láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ fún ìkọbiarasíi ẹ̀ nígbà t’óun wà ní Nigeria. Ó ti yọ Ukamaka kúrò nínú àwọn ọ̀rẹ́ẹ̀ ní Instant Messenger tí kò fi ní le mọ̀ tí ó bá wà lórí ayélujára. Kò sì tíì pè.

‘Bóyá ó tiẹ̀ dáa kó má pè,’ Chinedu sọ. ‘Kóo baà lè tẹ̀síwájú.’

Ukamaka dúró títí wọ́n fi padà dé inúu ibùgbée wọn, tí Chinedu sì ti gbé àwọ àpòo è lọ sínú ilé tó sì ti padà sọ̀kalẹ̀ wá, kó tó ní, ‘Ṣé o mọ̀, kò rọrùn tó bóo ṣe ròó yẹn o. Oò mọ bó ṣe rí láti nífẹ̀ẹ́ olóríburúkú kan.’

‘Mo mọ̀ o.’

Ó wòó, ó wọ aṣọ kannáà tó wọ̀ lọ́sàn ìjọ́ tó kọ́kọ́ kànlẹ̀kùun ẹ: jínsì àti swẹ́tà kan tó rọ̀ lọ́rùn, tí wọ́n kọ Princeton sí lára, ní àwọ̀ ọsàn.

‘Oò tíì sọ ǹkankan nípa ẹ̀ rí,’ Ukamaka sọ.

‘Ìwọ náà ò bèèrè rí.’

Ó gbé sandwich ẹ̀ sórí abọ́, ó sì jókòó ní tábílì ìjẹun. ‘Mi ò mọ̀ pé nǹkankan wà láti bèèrè. Èrò mi ni pé wàá kàn sọọ́ fún mi ni.’

Chinedu ò sọ ǹkankan.

‘Óyá, sọ fún mi. Sọ fún mi nípa ìfẹ́ yìí. Ṣé níbí ni àbí nílé?’

‘Nílé. Mo wà pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin náà fún ó fẹ́ẹ̀ tó ọdún méjì.’

Àsìkò náà wà nídàákẹ́jẹ́ẹ́. Ukamaka mú ìnuwọ́ kan nílẹ̀, ó sì ríi pé òun ti mọ̀ látinúwá tẹ́lẹ̀, bóyá láti ìbẹ̀rẹ̀ gaan. Ṣùgbón, nítorípé ó rò pé Chinedu fẹ́ kí òun fi ìyàlẹ́nu hàn, ó ní, ‘Oh, àṣé okùnrin-afẹ́kùnrin ni ẹ́.’

‘Ẹnìkan sọ fún mi nígbàkanrí pé èmi ni ọkùnrin-afẹ́kùnrin tó jọ ọkùnrin-afẹ́bìnrin jùlọ tí òún mọ̀. Mo kórìíra ara mi fún bí mo ṣe fẹ́ràn àpéjúwe yẹn.’ Ó ń rẹ́rìín músẹ́; ara ẹ̀ẹ́ balẹ̀.

‘Óyá sọ fún mi nípa ìfẹ́ yìí.’

‘Orúkọ ọkùnrin náà ni Abídèmí. Bí Chinedu ṣe pe orúkọ yẹn, Abídèmí, jẹ́ kí Ukamaka rántíi bíi kí èèyàn gbáralé iṣan tó ń rò’yàn, ara ríró tí èèyàn ṣe fúnra ẹ, tó sì mú inú ẹ̀ dùn.

Ó sọ̀rọ̀ ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, pẹ̀lúu àìkọbiara sí àwọn kókó tí Ukamaka rò pé kò ṣe pàtàkì — ṣé Ọjọ́rú ni àbí Ọjọ́bọ ni Abídèmí múu lọ sí ilé ijó aládàáni ti àwọn ọkùnrin-afẹ́kùnrin níbi tí wọ́n ti bọwọ́ pẹ̀lúu ààrẹ orílẹ̀-èdè àtijọ́ kan? — Ukamaka sì rò pé ìtàn yìí jẹ́ èyí tí kò tíì sọ púpọ̀ ní kíkún, tàbí tí kò tíì sọ fún ẹnìkankan rí.

Òṣìṣé bánkì ni Abídèmí jẹ́, ọmọ Ẹni Ńlá kan ni tó ti lọ sí yunifásitì ní Ìlú Ọba, irú ọkùnrin tó máa ń wọ bẹ́lítì aláwọ pẹ̀lú àràmọ̀ndà lógò bíi bọ́kù. Irú ìkan báyìí ló wọ̀ nígbà tó wá sí ilé iṣẹ́ onífóònù alágbèéká níbi tí Chinedu ti ń ṣiṣẹ́ aṣọ̀yàyà oníbàárà. O tiẹ̀ fẹ́ẹ̀ yájú, tó ń bèèrè pé ṣé kò sí ẹnìkan nípò àgbà t’óun lẹ̀ bá sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n Chinedu kò ṣe iyèméjì irú ojú tí wọ́n fún ara wọn wò, irú dídùn inú tí kò tíì rí rí láti ìgbà ìbáṣepọ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú atọ́kùn-ilé-ìwé fún eré ìdárayà kan nígbà tó wà ní ilé ìwé girama. Abídèmí fúun ní káàdì ẹ̀, o sì sọ ní kánmọ́, ‘Pè mí.’ Bí Abídèmí yóò ṣe darí ìbáṣepọ̀ yìí nìyẹn fún ọdún méjì tó tẹ̀lée, tó fẹ́ mọ ibi tí Chinedu lọ àti oun tó ṣe, tó ń ra mọ́tò fúun láì bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀, tí èyí fi wà ní ipò àti máa ṣàlàyé fún ẹbí àti ọ̀rẹ́ ẹ̀ ibi tó ti ra Honda tuntun lójijì, pípèé láti tẹ̀lée lọ sí ìrìn àjò afẹ́ lọ sí Calabar àti Kaduna láìfúun ju ọjọ́ kan láti ròó lọ, àti fífi ọ̀rọ̀ burúkú ránṣẹ́ lóríi fóònù nígbà tí Chinedu ò bá rí ìpèe rẹ̀ gbé. Síbẹ̀, Chinedu fẹ́ràan dídìmọ́ni yìí, ìjípépé ìbáṣepọ̀ náà tó gba ara àwọn méjèèjì kan. Àfi ìgbà tí Abídèmí sọ pé òun ti fẹ́ gbéyàwó. Orúkọ ẹni tó fẹ́ fẹ́ ni Kẹ́mi; àwọn òbí àwọn méjèèjì sì ti mọra tipẹ́tipẹ́. Wípé wọn ò le ṣàìmáṣe ìgbéyàwó jẹ́ oun tó ti yé àwọn méjèèjì tẹ́lẹ̀. Bóyá kò sì sí oun tíì bá yàtọ̀ bí Chinedu ò bá tíì pàdé Kẹ́mi níbi ayẹyẹ àjọ̀dún ìgbéyàwó àwọn òbí Abídèmí. Kò wulẹ̀ fẹ́ lọ tẹ́lẹ̀ — ó máa ń yẹra fún àwọn ayẹyẹ ẹbí Abídèmí — ṣùgbọ́n Abídèmí ní dandan ni, wípé òun ò lè borí bí ìrọ̀lẹ́ náà ṣe gùn tó àfi tí Chinedu bá wà níbẹ̀ nìkan. Abídèmí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn tó dàbí ohun tí a fi ẹ̀rín tẹ́lẹ̀ rẹ̀ nígbà tó fi Chinedu hàn sí Kẹ́mi gẹ́gẹ́ bíi ‘ọ̀rẹ́ mi gidi’.

‘Chinedu máa ń mu ọtí jù mí lọ,’ ni Abídèmí sọ fún Kẹ́mi tó wọ irun dídì òyìnbó àti aṣọ aláwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú rẹ̀ aláìlápá. Ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Abídèmí, ó sì ń nawọ́ lóòrèkóòrè láti gbọn nǹkan kúrò lára bùbá rẹ̀, láti báa bu gílásì ọtí ẹ̀ kún, lái gbọ́wọ́ lée lórúnkún. Ní gbogbo ìgbà náà, gbogbo ara ẹ̀ ló dúró digbì tó bá tiẹ̀ mu, bíi ẹni tó ṣetán láti ta gìrì dìde láti ṣe ounkóun tó bá gbà láti mú inú àfẹ́sọ́nà ẹ̀ dùn. ‘O ní máà níkùn ńlá ti bíà àbí?’ Abídèmí sọ, pẹ̀lú ọwọ́ ẹ̀ lórí itan tọ̀ún: ‘Ọkùnrin yìí á ní tiẹ̀ k’émi tó ní tèmi, mo ń sọ fún ẹ.’

Chinedu rẹ́rìín músẹ́ pẹ̀lú ìnira. Orí ti bẹ̀rẹ̀ sí ń fọ́ọ. Ìbínú rẹ̀ sí Abídèmí sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bú gbàmù. Bí Chinedu ṣe ń sọ èyí fún Ukamaka, bí ìbínú ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí ṣe ‘fọ́ọ lórí’, Ukamaka ṣàkíyèsí bí ara ẹ̀ ṣe ti le tó.

‘Ó wù ẹ́ kó jẹ́ pé oò pàdé ìyàwó ẹ̀, ‘ Ukamaka sọ.

‘Rárá. Ó wù mí pé kó tiẹ̀ rúu lójú díẹ̀.’

‘Ó dá mi lójú pé bẹ́ẹ̀ ló rí’

‘Kò rí bẹ́ẹ̀. Mo wòó lọ́jọ́ yẹn, bó ṣe ń ṣe pẹ̀lú àwa méjèèjì níbẹ̀, tó ń mu ọdẹ́kù, tó ń ṣe yẹ̀yẹ́ nípa mi fúun àti nípa ẹ̀ fún mi, mo dẹ̀ mọ̀ pé ó máa lọ síbùsùn ẹ̀, á dẹ̀ sùn dáadáa lálẹ́. Táa bá tẹ̀síwájú ni, ó máa wá máa bá mi lọ́sàán, á dẹ̀ tún padà lọ bá òun nílé lálẹ́, á dẹ̀ sùn falala dáadáa ní gbogbo ìgbà. Ó wù mí pé kó má lè sùn dáadáa nígbà míì.’

‘O wá dẹ́kùn ẹ̀?’

‘Inú bíi gidi. Kò yée ìdí tí mi ò lè fi ṣe oun tó fẹ́.’

‘Báwo lèèyàn kan ṣe le sọ pé òún fẹ́ràn ẹ, tá dẹ̀ wá fẹ́ ṣe nǹkan tó mú inúu tiẹ̀ nìkan dùn?’ Bí Udenna ṣe rí nìyẹn.’

Chinedu rún ìrọ̀rí tó gbé lé’tan. ‘Ukamaka, kìí ṣe gbogbo nǹkan ló jọ mọ Udenna.’

‘Mo kàn ń sọ ni, pé Abídèmí dàbí Udenna díẹ̀. Bóyá irú ìfẹ́ bẹ́yẹn ò yé mi ni ṣá.’

‘Bóyá kìí ṣè’fẹ́,’ Chinedu sọ, ó sì dìde lọ́gán láti orí àga. ‘Udenna ṣe eléyìí fún ẹ, Udenna ṣe tọ̀ún fún ẹ, ṣùgbọ́n kílódé tóo fi gbà kó ṣe bẹ́ẹ̀? Kílódé tóo fi gbà fúun? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti rò bóyá kìí ṣe ìfẹ́?’

Ohùn ẹ̀ mọ́rẹ́lọ́wọ́ bíi t’ọlọ́kàn líle, dídún ẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí à àyàa Ukamaka já fún ìṣẹ́jú àáyá kan, kó tó ṣẹ̀ wá bínú, tó sì ní kó bọ́ síta.

Kó tó di ọjọ́ yẹn, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣàkíyèsí àwọn nǹkan àràmọ̀ndà nípa Chinedu. Kìí ní kóun tẹ̀lée lọ sínú ibùgbé ẹ̀. Àti pé lẹ́ẹ̀kanrí, lẹ́yìn tí ó sọ fúun inú ibùgbé tó ń gbé, ó wo inú àpótí ìfilẹ́tàsí níbẹ̀, ó sì yàá lẹ́nu pé kò ní orúkọ bàbá ẹ̀ lára; olùṣàkóso ilé tí wọ́n ń gbé ti múu ní dandan pé orúko gbogbo ayálégbé ni kó wà lórí àpótí ìfilẹ́tàsí. Chinedu kò dàbí ẹni tó máa ń lọ s’ọ́gbà ẹ̀kọ́; ìgbà ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo tó bèèrè ìdí ẹ̀ lọwọ́ ẹ̀, kò dáhùn tààrà, èyí tó fihàán pé kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.

Kò ní báa sọ̀rọ̀ mọ́, ó sọ fúnra ẹ̀; ọmọ oko gidi ni ọkùnrin yẹn, tí kò sì lẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n Ọjọ́ Àìkú dé, ó sì ti mọ́ọ lára láti máa gbée lọ sí ilé ìjọsìn ní Lawrenceville kó tó máa lọ tiẹ̀ ní Òpópónà Nassau. Ó ń wùú pé kó wá kànlẹ̀kùn ẹ̀, ó sì mọ̀ pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ìbẹ̀rù kàn múu lọ́kàn lọ́gán pé Chinedu lè lọ bèẹ̀rè lọ́wọ́ elòmíì nínú ibùgbé ẹ̀ láti jáa sílẹ̀ nilé ìjọ́sìn. Nítorípé ó rí pé ìbẹ̀rù ẹ̀ yìí ń di ìpáyà, ó lọ sókè, ó sì kàlẹ̀kùn ẹ̀. Ó pẹ́ díẹ̀ kó tó ṣílẹ̀kùn. Ó dàbí ẹni tó ti rẹ̀; ojú ẹ̀ wà ní àìfọ̀, ó sì gbẹ.

‘Má bìnú,’ Ukamaka sọ. ‘Ṣé o fẹ́ kí n já ẹ sílẹ̀ ní ilé ìjọ́sìn?’

‘Rárá.’ Ó fọwọ́ pèé wọlé. Inú ilé ẹ̀ ò ní ǹkan púpọ̀, ó ní àga ìsinmilé, tábìlì, àti tẹlifísàn kan; a to àwọn ìwé lé ara wọn lórí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.

‘Wòó, Ukamaka, mo ní láti sọ oun tó ń ṣelẹ̀ fún ẹ. Jókòó.’

Ó jókòó. Wọ́n ń fi àwòrán eré ọmọdé kan hàn lórí móhùnmáwòrán. Bíbélì kan wà lórí tábìlì tó dojú bolẹ̀, pẹ̀lú ife oun tó dàbíi kọfí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀.

‘Mi ò sí nípò mọ́. Visa mi parí lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn. Ilé tí mo ń gbé yìí, ọ̀rẹ́ mi kan ló nií. Ó wà ní Peru fún simẹ́sítà yìí, ó dẹ̀ ní kí n wá gbé ibi títí màá fi kó ara mi yọ.’

‘Oò kí ń ṣe akẹ́kọ̀ọ́ níbí ní Princeton?’

‘Mi ò sọ pé mo jẹ́ ìkan.’ Ó yípadà, ó sì pa Bíbélì rẹ̀ dé. ‘Àwọn Elétò Ààlà Ìlú á tó fún mi níwèé máa-lọ-ilé-ẹ láìpẹ́. Kò si’ẹ́nìkankan nílé tó mọ oun tó ń ṣẹlẹ̀ gangan. Mi ò tíì le fi owó ju díẹ̀ lọ ránṣẹ́ sí wọn láti ìgbà tí mo ti pàdánù iṣẹ́ ìkọ́lé mi. Abẹ́ẹ tábìlì ni ọ̀gá mi ti ń sanwó fún mi, ṣùgbọ́n ó ní òun ò fẹ́ wàhálà nísìnyí tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa lílọ gbá àwọn ènìyàn mú lẹ́nu iṣẹ́ wọn.’

‘Ṣóo ti gbìyànjú láti wá àgbẹjọ́rò?’ ó bèèrè.

‘Mi ò kúkú lẹ́jọ́ rò.’ Ó ń gé ètè rẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ, Ukamaka ò sì tíì ríi rí kó rí bí ẹni tí kò dáralóju láti wò báyìí rí, pẹ̀lú gbogbo ẹran ara ojú ẹ̀ tó ń ṣe kùrukùru àti ojú tó ṣókùnkùn.

‘Oò ṣeé wò o. Oò tíì jẹun púpọ̀ láti ìgbà tí mo ti rí ẹ,’ Ukamaka sọ, ó sì ń ro gbogbo ọ̀sẹ̀ t’óun ti lò t’óun fi ń sọ̀rọ̀ nípa Udenna, tí Chinedu sì ń yọnu nípa bí wọ́n ṣe máa dáa padà sílé.

‘Mo ń gbààwẹ̀.’

‘Ṣó dá ẹ lójú pé oò fẹ́ kí n já sílẹ̀ nilé ìjọsìn?’

‘Mo ti pẹ́ ná.’

‘Tẹ̀lé mi lọ sílé ìjọsìn tèmi nígbà yẹn.’

‘O mọ̀ pé mi ò fẹ́ràn Ilé Ìjọsìn Àgùdà, pẹ̀lú gbogbo kíkúnlẹ̀ àti dídúró àti bíbọ òrìṣà wọn yẹn tí mi ò rò pé ó ṣe pàtàkì.’

‘Lẹ́ẹ̀kan yìí ná.’

Ìgbà tó yá, ó dìde, ó fọ ojú ẹ̀, ó sì pààrọ̀ aṣọ. Wọ́n rìn lọ sínú ọkọ̀ láì sọ̀rọ̀. Kò tíì ròó láti sọ fún Chinedu nípa ìgbọ̀nrìrì tó ṣẹlẹ̀ sóun nígba tí Chinedu ń gbàdúrà lọ́jọ́ kìínní, ṣùgbọ́n nítoríi pé ó ń fẹ́ ǹkan pàtàkì tó máa fi hàán pé kò dá dúró; wípé ó yé òun bó ṣe máa ń rí kí èèyàn má mọ ọjọ́ iwájú, láti má ní ìdarí nípa oun tó máa ṣẹlẹ̀ síi lọ́jọ́ ọ̀la — àti nítorípé kò kúkú tiẹ̀ mo oun míì láti sọ — ó sọ fúun nípa ìgbọ̀nrìrì yẹn.

‘Ó yanilẹ́nu,’ Ukamaka sọ. ‘Bóyá ìgbọ́kànsókè mi nípa Udenna ló dẹ̀ fàá.’

‘Ààmì ni láti ọ̀dọ̀ ọlọ́run,’ Chinedu sọ pẹ̀lú ìgboyà.

‘Kíni ànfàní ìgbọ̀nrìrì mi gẹ́gẹ́ bí ààmì láti ọ̀dọ̀ ọlọ́run?’

‘O ní láti yé rò pé bí èèyàn ni ọlọ́run. Ọlọ́run ni ọlọ́run.’

‘Ìgbàgbọ́ ẹ, bí ìjà ló ṣe máa ń rí.’ Ó wòó. ‘Kíni ànfàní pé ọlọ́run jẹ́ ààlọ́ àpamọ̀ tí ò yé’èèyàn?’

‘Nítoríi b’ọ́lọ́run ṣe rí ni. Tó bá ti yé ẹ pé irú b’ọ́lọ́run ṣe jẹ́ kìí ṣe irú ènìyàn, gbogbo ẹ̀ á yé ẹ,’ Chinedu sọ, ó sì ṣí’lẹ̀kùn láti jáde kúrò nínú ọkọ̀. Irú ọlá wo ni láti ní irú ìgbàgbọ́ báyìí, tí kìí bèèrè ọ̀rọ̀, tó gbójú, tí kò sì ní sùúrù, Ukamaka rò. Síbẹ̀, nǹkankan wà nípa ẹ̀ tó ṣe ẹlẹgẹ́; bíi pé Chinedu kò lè ronú nípa ìgbàgbọ́ àfi lọ́nà líle, àfi bíi pé gbígbà pé ààyè wà láàárín yóò múu da gbogbo èyí tó kù nù.

‘Oun tóo sọ yé mi,’ ó dáhùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yée rárá.

Níta ilé ìjọ̀sin olókuta aláwọ̀ eérú, Patrick Fadá ń kí àwọn èèyàn, pẹ̀lú irun ẹ̀ tó ń tàn bíi fàdákà ní ìmọ́lẹ̀ ìyálẹ̀ta.

‘Mo ti mú ẹnìkan tuntun wá sínú túbú ẹ̀yà Kátólíkì, Fadá P,’ Ukamaká sọ.

‘Ààyè pọ̀ nínú túbú o,’ Patrick Fadá dáhùn, ó sì gba Chinedu lọ́wọ́.

Inú ṣọ́ọ́ṣì ṣókùnkùn, ó kún fún àwọn ànjọ̀nú ohùn àti oun àìyé, àti òórùn àbẹ́là lábẹ́nú. Wọ́n jókòó papọ̀ s’ẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn láàárín, lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin kan tó gb’ọ́mo dání.

‘Ṣẹ́ o fẹ́ràan ẹ̀?’ Ukamaka sọ l’óhùn ilẹ̀.

‘Àlùfáà? Ó dà bí ọmọlúàbí.’

‘Àní fẹ́ràn fẹ́ràn.’

‘Ah, ọlọ́run ọba Jehofa ò. Rárá o!’

Ó ti múu rẹ́rìín músẹ́. ‘Wọn ò ní dá ẹ padà sílé, Chinedu. Àá wa ọ̀nà síi. Bẹ́ẹ̀ni.’ Ó fún ọwọ́ ẹ̀ mọ́ra, ó sì mọ̀ pé inú ẹ̀ dùn bí òún ṣe tẹnu mọ́ ‘àá’.

Ó tẹ́ súnmọ́ọ. ‘Ǹjẹ́ o mọ̀, èmi náà nífẹ̀ẹ́ Thomas Sankara pẹ̀lú.’

‘Rárá o!’

‘Mi ò tiẹ̀ mọ̀ pé orílẹ̀-èdè kan wà tó ń jẹ́ Burkina Faso ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfríkà àf’ìgbà tí olùkọ́ mi ní ilé ìwé girama sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tó sì mú àwòrán ẹ̀ wá. Mi ò le gbàgbé bí ìfẹ́ ṣe wọ̀ mí lójú tó nítorí àwòrán inú ìwé ìròyìn nìkan.’

Wọ́n kọ́kọ́ ń bo ẹ̀rín wọn mọ́lẹ̀; ìgbà tó yá, wọ́n kúkú jẹ́ kó jáde pẹ̀lú ọ̀yàyà; wọ́n ń f’ara gbá’ra wọn, obìnrin tó gb’ọ́mọ dáni sì ń wò wọ́n.

Àwọn akọrin ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin. Ìkan nínú àwọn ọjọ́ Sọ́ndè yẹn ni tí àlùfáà máa ń fi omi mímọ́ bùkún gbogbo ìjọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìsìn. Patrick Fadá ń rìn lọ rìn bọ̀, ó ń wọ́n omi sí àwọn ènìyàn lójú pẹ̀lú nǹkan tó dàbí ohun tí wọn fi ń bu iyọ̀ s’óríi tábìlì. Ukamaka ń wòó, ó sì ro bí ìjọsìn Kátólíkì ṣe lọ́wọ́rọ́ tó ní America; tó jẹ́ pé tó bá jẹ́ ní Nàìjíríà ni, ìṣẹ́pẹ́ igi kan aláwọ̀ ewé láti ara igi mọ́ngò ni àlùfáà á kì bọ inú garawa omi mímọ́ tí ọmọ kékeré ìsìn kan tó ń làágùn tó sì ń kánjú máa ń gbé dání; tó jẹ́ pé á ti rìn lọ rìn bọ̀, tí á máa da omi pàṣà, tá sì máa pòòyì pẹ̀lú omi mímọ́ tó ń rọ̀ bí òjò; tí gbogbo àwọn tó wa nínú ìsìn á sì ti tutù; àti bí, pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ àti ìṣààmì àgbélébú, gbogbo wọn á ti rò pé àwọ́n rí ìbùkún gbà.


Some Thoughts on Translation into Yorùbá

Doing translation work into Yorùbá has the added benefit of forcing a number of questions to the fore of my mind. Why, for instance, are there more grants and opportunities for translating indigenous African[2] literature into English[3] and fewer ones for translating both classic and contemporary work written in English, sometimes by Africans themselves, back into the local languages? The biggest example of this open question is the absence of a published Igbo translation of Chinua Achebe’s Things Fall Apart. It is as if a consensus has been agreed upon at some indeterminate place, that only speakers and readers of English deserve or desire to read classic or contemporary literature from all corners of the world.

This is not the case, of course, but it is an argument that is very hard to make in the absence of a concrete audience, in these local language spaces, consuming and engaging with literature in the mother tongue. In Nigeria today, the publishing industry for local language literature is virtually non-existent, with the little one finds in bend-down bookstores coming often from self-published works of the few remaining authors from the golden days of indigenous language publishing. There are no new stars. No contemporary authors. No new works, and certainly no industry around selling, marketing, consuming, discussing, reviewing, and engaging them. No new movie adaptations, no blockbuster deals. In short, no industry. If nobody is reading them, then why write them at all?

But people exist in Nigeria today who can read fluently in Yorùbá and Igbo and Hausa and Edo and a number of other Nigerian languages. They exist in my family. They exist online. I’ve met many of them on the streets and in classrooms and conferences. So why have they not formed a critical mass to attract (or invent) authors that write to them in a language they speak? I don’t know. Maybe they have become used to the idea that literature could only exist in English, and thus don’t actually care. Maybe they’ve forgotten the pleasure they had reading literature in their languages, or maybe they actually never did. Fágúnwà’s books were first published in the early fifties, after all, so whoever was old enough to enjoy them then is probably a grandfather or grandmother today, and probably doesn’t spend as much of their time on the internet where much of contemporary literature is being produced and consumed.

But, assuming that creative writers exist interested in filling the space, how would they write? The practicality of actually writing much before publishing in Yorùbá — to use an example I’m most familiar with — is actually problematic. Until we released, through my project at YorubaName.com, the first free tonemarking software in Igbo and Yorùbá in 2015, and later for mobile devices through the Google GBoard app in 2017, there was no place online where one can find a tool of such nature that is free, easy and intuitive to use, and had the required diacritics. Typewriters are no longer a thing, so any piece of literature written first longhand would likely have died on the way to the publisher due to the absence of a proper word processing tool. So, in some way, the dearth of required technology was already a problematic impediment. The publishers who wanted to take a chance on such work would have become discouraged by the amount of work it took, along with the risk of never even actually finding the audience in the end, and given up.

Now, the practicality of the translation work I’ve just completed here forces me into a different kind of contemplation: that the language I speak as a first language — Yorùbá — is in need of some kind of an upgrade, if only in its writing rules. So much has happened since the last time such an intervention happened that the current state of the language calls for another one, especially in order to deal with the internet/electronic century. In its history as a written language, there have been only two known updates to its orthography. The first, which was less a prescriptive one, being the first work in that direction, are the translations of Bishop Àjàyí crowther, the early missionary pioneer linguist and translator who helped bring the Bible and the early Christian hymns into Yorùbá. The second came in the late ‘60s and early ‘70s, through the work of Ayọ̀ Bámgbóṣé, now an emeritus Professor of Linguistics at the University of Ìbàdàn whose work in 1974 lays down some of the rules we still use today.

The absence of adequate systems (via Unicode, for instance) for typing in Yorùbá on the internet is already a first impediment. The insufficiency of more recent ones created to deal with the most elementary problems is a separate problem. A name like “Adenike,”[4] for instance, can only be properly written without tone marks if one wanted to stay faithful to both its tonal and lexical components. In the absence of one or the other, it would be better rendered as Adéníkẹ̀ẹ́ or Adéníìkẹ́, which fails lexically, as the name is rarely ever written like that. The version as Adéníkẹ́ fails, worse, phonologically. The caron, a diacritic that combines both the low and the high tone [ˇ], or a circumflex combining a high and a low tone [ ˆ ], could easily solve the problem (thus “Adénîkẹ́” or “Adéníkě”[5]). But neither exists in most modern typing systems nor in the recommended rules from the 1974 orthography.

There were other problems like this that I encountered in translating this work, which presented a different kind of professional challenge and pleasure rolled into one (different from the one derived, in the first place, by the simple act of bringing into the Yorùbá language a literary work of a Nigerian writer of a different language group which first travelled through the medium of English before it came back into another Nigerian language, one that the writer may not even speak. It has a kind of delight). It is having to decide between writing third-person pronouns in Yorùbá as autonomous lexical items as have been previously recommended or accepted (e.g., fún-un, fihàn-án, and, in some other cases, rẹ́rìn-ín, etc.) or having them as blended parts of the verb as have been used in other instances (like wòó, jẹẹ́, múu, etc.).

Language tends towards simplification, we’ve often been told. In speech, these grammatical markers are often less in one’s face than writing often seems to make them appear, and strict prescriptive rules have only done more to prevent many speakers from writing the language for fear of stepping over thick intractable lines of unforgiving grammarians. Why, I thought, don’t we allow those who choose to write the language evolve their own intuitive ways of communication, thus letting loose what will surely be a period of high fecundity for the growth of the language in literature? The closer the writing system gets to the normal everyday speaking patterns[6], the easier it will be for adoption for use by those to whom the only obstacle are the imaginary eyes of disapproving grammarians.

Therefore, in this work, you will find that I have deliberately tended, where I could, towards the rebellious. You will see ‘fúun’ instead of ‘fún-un’, ‘fi hàán’ instead of ‘fi hàn-án’ and ‘fẹ́ràan rẹ̀’ instead of ‘fẹ́ràn-an rẹ̀’ — hopefully sufficiently relevant as incremental chipping at the edges of old strictures to eventually invite a revision of many more rustic frames of our orthographical guardrails. There are many others: the use of ‘ẹ̀’, sometimes, instead of ‘rẹ̀’, or of the modern ‘dẹ̀’ for the auxiliary ‘has’ instead of the usual traditional ‘sì’ (the latter limited in use to character dialogues as a way to represent them as modern children of cosmopolitan language communities). These are all my ways of inviting new ways of writing in Yorùbá, showing that there is no one “right” way, as long as what we are doing is putting new writings in the hands of readers and consumers wherever the internet can find them.

Something else I realized, first to my consternation, then later to my delight at the challenge it took to overcome, was the significance of the absence of gender in Yorùbá pronouns. How does one specify, successfully, who is talking without having to mention their name every time it is their turn to speak? And how do you say “uncle” when the writer has not specified if it was a character’s mother’s brother or father’s brother, or whether they are the father or mother’s elder or younger brother? Also, when you say “sister” or “brother” in English, a Yorùbá listener does not know whether these siblings are older or younger than you. A literary translator then has to step in to provide a context that is neither self-evident nor satisfactory. As you will also find out, especially at a most crucial part of the story where the most important reveal happens, it was impossible to merely rely on the genderless pronouns of Yorùbá which — ironically, in other real life scenarios, a most positive invention ahead of its time, worthy of being celebrated in its contrast to European languages that currently struggle to deal with modern gender categorizations — would have made the momentous disclosure much less significant.


Kọ́lá Túbọ̀sún

Lagos, Nigeria.

Notes

    1. Ìtàn yìí ni a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bíi The Shivering nínú ìwée Chimamanda Adichie tí a pè ní “The Thing Around Your Neck” lọ́dúun 2009.

      This is a translation of Chimamanda Adichie’s short story “The Shivering” from The Thing Around Your Neck (2009) into Yoruba.return to text

    2. And global, other indigenous peoples’.return to text

    3. And other European, and already established languages.return to text

    4. There are other examples like “Oyebodé” or “Ayowunmi.”return to text

    5. Done with Google GBoard, but still quite unsuccessfully, as the last [e] with the caron is supposed to have a dot underneath it here. It doesn’t.return to text

    6. Yes, this can never really be effectively achieved, especially in formal writing, but in literature, it is certainly a noble and certainly admirable goal.return to text